Luke 12:35-38

Ẹ máa ṣọ́nà

35 a “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó. 36Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé: pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán. 37 bÌbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.
Copyright information for YorBMYO